Àgbéyẹ̀wò “Digital Nollywood” (Ọ̀ rọ̀ láti ẹnu àwọn àgbà òṣèré) àti “Ògbóǹtarìgì”

Abstract

Digital Nollywood jẹ́ iṣé ìwádìí dígítà tí ó bẹ̀ rẹ̀ ní 2018 láti ṣe àgbékalè ìtàn fíìmù ní Nàìjíríà. Ìlànà ìwádìí yìí ń ṣe àmúlò àwọn ohun àfojúrí àti àwọn ìwé àlẹ̀ móde tí wọ́ n fi ṣe ìpolówó àwọn fíìmù, pàápàá jù lọ ní ikọ̀ fíìmù tí a mọ̀ sí Nollywood. Fún iṣẹ́ Digital Nollywood, a rí àwọn ohun èlò àfojúrí àti ìwé àlẹ̀ móde wọ̀ nyí gẹ́ gẹ́ bíi iṣẹ́ ọnà tí ó wúlò fún ìṣèwádìí iṣẹ́ ìtàn Nollywood ní ọ̀ nà tí ó yàtò. Ní oríṣiríṣi ọ̀ nà, iṣẹ́ yìí ń lo àwọn ìwé àlẹ̀ móde wọ̀ nyí láti ṣe àgbékalè ìtàn àwọn ohun ìkéde tí ó ṣe àmúlò àwọn nǹkan tí ó jé tiwantiwa. Ní ìtají sí bí àwọn ohun èlò àfojúrí àti ìwé àlẹ̀ móde wọ̀ nyí ti ṣe ń di àwátì, iṣẹ́ yìí ń ṣe àmúlò àwọn ìtẹ̀ síwájú tí ó pemọ́ ìmọ̀ ẹ̀ rọ láti wo àwọn ọ̀ nà míràn tí a lè gbà se iṣẹ́ ìwádìí ìtàn tàbí se àgbéyèwò àṣà àti ìṣe ní ilè Africa. Nípasẹ̀ àmúlò ohun àgbéjáde ayélujára, Digital Nollywood ní èrò láti di iṣẹ́ ìwádìí dígítà tí ó ń ṣe ìdásí àti ìtẹ́ pẹpẹ ìwé àlẹ̀ móde àwọn fíìmù Nollywood nípasẹ̀ àgbàjọ àwọn ìwé wọ̀ nyí ní orí pẹpẹ Omeka.

 

https://doi.org/10.32473/ysr.8.1.134097
PDF
Creative Commons License

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.

Copyright (c) 2023 ‘Gbenga Adeoba

Metrics

Metrics Loading ...