Abstract
Akiyesi pe opo onimo ni won ti sise lori oriki orile. Awon kan fi oju tiori imo ibagbepo awujo, imo isewadii-fininin-isedaniyam (anthropological method), ifoju-aato-wo, ifoju-ihun-wo, amo ko si eni to ti i lo tiori imo abinibi (indigenous knowledge) lati yiri oriki orile wo. Eredie ree ti a wa fi lo tiori imo abinibi lati wo bi awon Yoruba se n samulo awon nnkan ti o wa larowoto ati ayika won. Agbalo agbabo ni pe a ri eri pe opo imo ibile lo je yo ti o si hande ninu oriki orile, paapaa awon eyi ti ijoba ile Naijiria i ba fi pese ise fun ogoro odo ti won fese gba igboro kiri. Lara imo abinibi ti a ri naa ni ise ona sise, ile kiko lona ibile, aso hibun ati ise tewe-tegbo.
This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.