Àgbéyẹ̀wò Ipa Èdè, Àṣà, àti Lítíréṣọ̀ Yorùbá Nínú ọ̀gbagadè Ìtàn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Abstract

Ede, asa ati litireso je mayami eta-oko to n safihan idanimo awon eniyan kan. Ni orile-ede Naijiria, ede, asa, ati litireso n ko ipa pataki ninu itan won lati igba ti won ti da ekun ariwa ati guusu papo ni odun 1914. ninu aoileko yli, a lo tiori imo ajemotan-tuntun ati tiori imo asa lati sayewo ipa ti ede, asa ati litireso n ko ninu itan, iselu, ibagbepo-eda, eto-oro-aje, esin, ati eto-eko ni orile-ede Naijiria. Arifayo ti a ri ni pe: asa duro bi aaringbungbun fun iselu. Ipo ti awon oba ko ninu iselu olona-ero Lord Lugard si fi pataki asa mule. Bi o tile je pe awon asejoba-amunisin bu enu ate lu ede Yoruba, igbende re ti mu itesiwaju ba imo ero. Litireso Yoruba naa je ohun-elo-ija fun ifi-oju-amuwaye-eni lole ni Naijiria. Imugbooro ti ise ona ise owo, ise ona-alawomo litireso, tilu-tifon, ati fiimu n mu ba eto oro aje naa je jade. Ni ikadii, apileko yil fi idi re mule pe kiko ati mimo ede, asa, ati litireso Yoruba je ohun ti o ye ki a mu ni okunkundun fun igbelaruge asa, ki a si samulo re fun idagbasoke abanikale. 

https://doi.org/10.32473/ysr.v1i2.130151
PDF
Creative Commons License

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.