Kíkọ́ Àjòjì Ní Gírámà Èdè Yorùbá: Àkóónú Àti Ọgbọ́n-Ìkọ́ni

Abstract

O pon dandan lati wa ona ti awon ajoji ti won nifee lati ko ati lati mo ede Yoruba yoo gba ti yoo fi ro won lorun lai si pe kiko ede Yoruba n ko won lominu. Idi pataki ni pe ogooro ninu awon ti o fe ko ede yii ni o je wi pe ki i se fun siso nikan tabi kiko lerefee, bikose pe won fe ni imo ti o kun ti awon naa yoo fi le se bi omo bibi Yoruba. Eko gbigbona ni oro kiko girama ede je, o n fe suuru gidigidi. Nitori idi eyi, awa Oluko ede Yoruba ni lati wa ona ti yoo je ki kiko ati mimo ede Yoruba ati paapaa girama ede, dabi pe a n fi eran jeko. Ohun ti yoo je wa logun ju ninu ise yii ni pe a o wo bi a se le ko awon akekoo yii, ti won tun je ajoji, ni girama ede Yoruba lai si pe a le won sa lati ko ati lati mo ede yii. A o wo gbogbo awon ohun ti o ye ki awon akekoo mo ninu girama ede Yoruba, awon ipele ti o ye ki won ti mo on ati bi o ti ye ki a ko won ni ipele kookan. A o beere, a o si tun dahun idi ti awon ajoji fi nifee lati ko ati lati mo ede Yoruba. Gbogbo ohun ti o ye ki o wa ninu akoonu ti akekoo gbodo mo ni a o ye wo finnifinni. Leyin eyi, a o tun wo gbogbo ogbon ikoni ti a le lo ti yoo fi je ki kiko girama ede rorun fun wa lati ko, ki o si tun rorun fun awon akekoo lati mo. Leyin eyi, a o soro lekun-un rere lori bi o se ye ki a ko awon akekoo yii ni akodunnu ti yoo fi je ki ede Yoruba wu won lopolopo.

https://doi.org/10.32473/ysr.v1i2.130143
PDF
Creative Commons License

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.

Copyright (c) 2021 Harrison Adeniyi

Metrics

Metrics Loading ...