Abstract
Ijapa bo, o ni ohun ti eniyan ba moo se, bi idan nii ri. Amo sa, ki i le se ohunkohun lo dabi idan, igbaradi ati ipalemo to ye se pataki pupo. Ninu apileko yii, a o soro nipa okan pataki ninu awom eroja ti o se koko fun kiko ajoji ni ede ati asa Yoruba ni akoyege. Eroja yi ni ise ti oluko kookan gbodo se lati da orisi awon akekoo ti won wa ni kilaasi mo ati lati yara se amodaju orisi ona ti onikaluku won n gba kekoo paapaa julo ikede won. Awon itoka ti a se ninu apileko yii yoo da lorii gbogdo iriri ati akitiyan ti a ti n se fun igba die ti a ti nko orisiriawon ajoji ni ede ati asa Yoruba ni ilu Amerika. Laarin akoko yi, a ti ko awon akekoo yunifasiti ti o le nigba ni akoyege. Enikan ki i gbon tan. Yato si iriri tiwa, a o tun mulo lara imo awon ti won ti n ko ajoji ni ede ati asa Yoruba nile ati lokeere fun igba die lati fi kun gbogbo alaye inu apileko yi. Aleye awon rikan ti a ti ri pe o se koko, ti o si ti wulo ninu akiti-yan atiko awon ajoji lede ati lasa abinibi wa ni a se akojopo re sino apileko yii.
This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.