Igi Ńlá Wó: Ọlábìyí, Èèyàn Iyì Tí n Jẹ́ Yáì Sùn Kalẹ̀ Gbalaja!

Abstract

“Ọkùnrin lọ!

 Ọkùnrin lọ!

 Ò-bọ Sòkòtò f’ẹnu è sọlè ̣ ;̣

Ọkùnrin lọọọ!”

Igi dá nígbó;

Gbogbo igbó pa késekése!

Àgbà Òjọ̀ gbó ̣ n dolóògbé; ̣

 Ilé ìmò dìtàn poo! ̣

Gbogbo àgbáyé ń ṣòfọ̀ ọmọ Odùduwà tó sílè ̣ wò ̣ !̣

Bíkú bá pa’jú ẹni dé,

 Ẹgbé ẹni a sì máa wá rìrì kiri! ̣

Àwọn èèyàn tó màṣà tó mèdè, tó mẹni màṣà mèdè,

Gbogbo wọn ń dárò ẹni ire tó lọ!

Bí a bá pe’rí akọni,

 À sì fidá lalè!̣

Àgbà ńlá ló fó!̣

Kete omi ta gbé rodò, kómi ó lè wálé subú yékẹ́ ,̣

Kasán já;

Agbagbáṣo kò rígbà ṣo o!

Ìlú Ṣábèẹ́ àt’orílè ̣ -èdè Bìnì nìkan kó ̣ ló pàdánù ẹni ire tó lọ; ̣

Gbogbo ayé ló ń mímí èdùn ló ̣ kàn nítòsí àti lókèèrè réré! ̣

Ibi téégún ṣeré dé,

 Gbogbo wọn ni ò lè réégún mó!̣

Èkú nìkan ni gbogbo wa ń wò nílè ̣ !̣

Ẹyẹ sí, Ẹ

yẹ lọ;

Ìyé nìkan ló kù táaráyé ó máa wò l’é ̣ yìn ẹyẹ! ̣

 A-gbéni-rìnrìn-àjò-dé’bi- ó sunwòn ti té ̣ rí gbaṣọ!

 

 

https://doi.org/10.32473/ysr.v6i1.130108
PDF
Creative Commons License

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.

Metrics

Metrics Loading ...