Abstract
Iṣẹ́ yìí ṣe àgbéyẹ̀ wò ìyàtọ̀ tó wà nínú àṣà ìgbéyàwó ní ìlú Kákùmọ̀ sí ti agbègbè ilẹ̀ Yorùbá mìíràn; a fi tíọ́ rì ìfojú-àṣà-ìbílẹ̀ -wò àti tíọ́ rì ìṣẹ̀ tọ́ fábo ṣe àtẹ̀ gùn. A lo ọgbọ́ n ìfọ̀ rọ̀ wánilẹ́ nuwò, a sì ka àkọsílẹ̀ ìtàn ìlú Kákùmọ̀ . Àbájáde ìwádìí fi hàn pé àgbékalẹ̀ ètò ìgbéyàwó ìlú Kákùmọ̀ yàtọ̀ díẹ̀ sí ti ilẹ̀ Yorùbá yòókù. Lára ìyàtọ̀ náà ni: fífi pàṣán ìyàwó lé ọkọ ìyàwó lọ́ wọ́ , fífi àkùkọ adìyẹ pàrokò ìbálé àti dídi ìgbálẹ̀ lọ fún ọmọ nílé ọkọ. Tíọ́ rì ìfoju-àṣà-ìbílẹ̀ -wò tí a lò fi hàn pé ẹgba ìbẹ̀ rù ni baba fí lé ọkọ ọmọ rẹ̀ lọ́ wọ́ ; a kì í sì í fi ẹgba ìbẹ̀ rù na ọmọ ṣùgbọ́ n yóò jẹ́ kí ìyàwó ní ìbẹ̀ rù ọkọ lọ́ kàn. Ìlànà ìṣẹ̀ tọ́ fábo lòdì sí dídá ẹ̀ rù sí obìnrin lọ́ kàn bí irú èyí. Ìfẹ́ ló ṣe pàtàkì. Àpilẹ̀ kọ yìí dá a lábàá pé kí àwùjọ yí èrò wọn nípa ẹgba ìbẹ̀ rù padà.
This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.