Àgbéyẹ̀wò Ìlò-Èdè Nínú Orin Ìbílẹ̀ Ìlọrin

Abstract

Ọ̀kan pàtàkì tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn lára ẹ̀ka tí lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá pín sí ni orin jẹ́. Bárakú sì ní ọ̀rọ̀ orin láwùjọ ọmọ ènìyàn pàápàá jù lọ àwọn Yorùbá nítorí pé onírúurú ààyè ni orin ti máa ń jẹ jáde nínú ìgbésí-ayé wọn lójoojúmọ́. Bí àwọn akọrin àwùjọ bá sì ń ṣiṣẹ́ ọnà wọn, ìjìnlẹ̀ èdè tó jinná ni wọ́ n fi máa ń gbé e jáde tí yóò sì máa ṣàfihàn bí irú àwọn akọrin bẹ́ ẹ̀ ṣe gbọ́ èdè àti ìmọ̀ nípa àṣà àwùjọ tó ti ń kọrin nítorí pé ìpohùn ìbílẹ̀ èyí tí orin jẹ́ ọ̀ kan pàtàkì lára wọn dà gẹ́gẹ́ bí àwògbè tàbí díńgí tí a fi ń ríran rí àwùjọ. Ìlò-èdè tó jinná kò sì ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn kí àgbékalẹ̀ orin wọ̀nyẹn lè rídìí jòkó dáadáa kí wọ́n sì lè wu etí í gbọ́. Nínú iṣẹ́ yìí, a ṣe àgbéyẹ̀wò àtí àtúpalẹ̀ díẹ̀ lára àwọn ọnà-èdè tó ṣúyọ nínú àṣàyàn orin ìbílẹ̀ Yorùbá Ìlọrin bíi dàdàkúàdà, bàlúù, wákà, kèǹgbè, sẹnwẹlẹ, kàkàkí/bẹ̀ ǹbẹ́ , Orin ọlọ́ mọ-ọba Ìlọrin,orin agbè àti àwọn mìíràn. Lára àwọn ọnà-èdè tí a gbéyẹ̀ wò ni àwítúnwí, àfiwé, ìjẹyọ ẹ̀ ka-èdè, àyálò-èdè àti ipa ‘Creole’ nínú orin ìbílẹ̀ Ìlọrin. Iṣẹ́ yìí ṣàfihàn pé iṣẹ́ ọpọlọ tó jinná ni orin kíkọ àti pé àwọn ọnà-èdè tó máa ń ṣodo sínú wọn lóríṣiríṣi ní iṣẹ́ tí kálukú wọn ń jẹ́ láti túdìí òkodoro nípa àṣà, ìṣe àti èdè àwùjọ tí onírúurú àwọn orin náà ti ń jáde

https://doi.org/10.32473/ysr.v6i1.130101
PDF
Creative Commons License

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.

Metrics

Metrics Loading ...