Ìfarajọ-Èébú nínú Àwọn Àsàyàn Oríkì Yorùbá

Abstract

 Òkan pàtàkì lára lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá ni oríkì jẹ́, àwọn onímọ̀ lọ́kan- ̣ ò-jò kan ló sì ti wale ̣ ̀ jin lórí oríkì ṣùgbọ́n kò tí sí iṣẹ́ ìwádìí kan gbòógì tí ó ̣ jẹyọ lórí ìfarajọ-èébú nínú oríkì Yorùbá. Láti di àlàfo yìí, iṣẹ́ ìwádìí yìí fi tíọ́rì ìfìwádìí-sọ̀tumọ̀ ṣe àtẹ̀gùn láti ṣe àyẹ̀wò àwọn oríṣìí oríkì Yorùbá mẹ́ta tí ìfarajọ-èébú jẹyọ nínú wọn, èyí tí a ṣe àfàyọ wọ́n láti inú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí a ṣe àti iṣẹ́ àpilẹ̀kọ àwọn onímọ̀. Àwọn oríkì náà ni oríkì orílẹ̀, oríkì àmútọ̀runwá àti oríkì ìlú. Ìwádìí yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé gbogbo àwọn ìpèdè tí ó farajọ èébú àti ìtìjú fún àwọn ènìyàn ní àwùjọ Yorùbá ni wó n kì í ṣe èébú ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ ̣ ohun àmúyangàn, ohun ọlá àti ẹ̀yẹ ní ìgbà tí a bá ti sọ ó di oríkì tí a sì fi ń ki ̣ àwọn olóríkì. Ohun ti èyí ń tọ́ka sí ni pé, àwọn àṣà àti èrò Yorùbá nípa èébú àti àbùkù máa ń yípadà ní ìgbà tí a bá ṣàmúlò wọn gẹ́gẹ́ bí oríkì ní ilẹ̀ Yorùbá, torí kì í ṣe èébú mọ́ ṣùgbọ́n ìtọ́ka sí ìtàn àti ìṣe akọni olóríkì ni.

https://doi.org/10.32473/ysr.v6i1.130098
PDF
Creative Commons License

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.

Metrics

Metrics Loading ...