Ìṣọwọ́lò Ète Ìfèdèyàwòrán Nínú Ìpolówó Ọjà Lórí Rédíò

Abstract

 Ìpolówó ọjà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun èlò àdámọ́ ọjà títà àti rírà nílẹ̀ Yorùbá àti láwùjọ gbogbogboò. Ìpolówó ọjà bẹ̀rẹ̀ nípaṣẹ̀ kí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ta tàbí ṣe irúfẹ́ ohun tó jọra wọ́n. Èyí ló mú kí a máa wá ète láti polówó. Ọ̀kan lára ète ìpolówó ni èdè ìpolówó jẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ní ẹ̀ka ìmọ̀ èdè Yorùbá, àti ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ àti ìṣàmúlò ède ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí èdè Yorùbá, ìpolówó-ọjà, ọ̀nà àti àwọ́n ète ìpolówó kan. Síbẹ̀, ìwọ̀nba péréte ní iṣẹ́ tó wà lórí ìpolówó orí rédìò àti èdè. A tún ṣàkíyèsi pé kò sì iṣẹ̀ lórí àmúyẹ ìfójú-ìhun-à-so-pọ̀-mọ́- ìṣẹ̀lẹ̀-àwùjọ-wo ìṣọwọ́lò ète ìfèdèyàwòrán nínú ìpolówó ọjà lórí rédíò. Èróńgbà wa ni láti ṣe àgbéyẹ̀ wò ìpolówó ọjà lórí rédíò pẹ̀ lú ète àti ṣe àfihàn bí àwọn apolówó ṣe máa ń ṣọwọ́ lo ìfèdèyàwóràn nínú àwọn ìpolówó orí rédíò. A ṣe àṣàyàn ìpolówó ọjà mẹ́ jọ lórí àwọn rédíò tí ó ṣábà máa ń ṣe àmúlò èdè Yorùbá fún àgbékalẹ̀ ètò wọn nílùú Ìbàdàn nípínlẹ̀ Ọ̀yọ́ . A mọ̀ -ọ́ n-mọ̀ yan àwọn ìpolówó yìí nítorí àwọn ní wọ́ n ní àmúlù-màlá èdè tó mọ́ níba. A tún fi ọ̀ rọ̀ wá àwọn ènìyàn méjì tó wà ní ẹ̀ ka ìpolówó ọjà lórí rédíò lẹ́ nu wò láti ṣe ìwádìí nípa ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ rédíò, ìpolówó ọjà lórí rédíò àti bí a ṣe ń ṣe àgbékalẹ̀ àti ìgbéjáde ìpolówó ọjà lórí rédíò. Lẹ́ yìn tí a kó àwọn ìpolówó yìí jọ tí a sì ṣe àkọsílẹ̀ wọn, a ṣe amúlò tíọ́rì ìfojú-ìhun-à-so-pọ̀-mọ́-ìṣẹ̀lẹ̀-àwùjọ-wò láti ṣe àwàjinlẹ̀ ìtúpalẹ̀ wa. Tíọ́rì yìí wà fún ṣíṣe àfihàn bí a ṣe ń hun ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ mọ́ inu iṣẹ́ aláwòmọ́-lítíréṣọ̀. Ìwádìí wa fi han pé; lákọ̀kọ́ọ́, ète ìfèdèyàwòrán ni ó pọ̀ jù nínú ìhun ìpolówó orí rédíò, èyí tí ó hànde nínú bí wọ́ n ṣe hun èdè àwọn ìpolówó ọjà náà. Èkejì ní pé àwọn ọ̀ nà ìṣọwọ́ lòèdè kan wà tí apolówó ṣábà máa ń lò láti fi yàwòrán inú nínú ìpolówó ọjà lórí rédíò, lára wọn ni òwe, àkànlò-èdè, ìfìrógbóyeyọ, àsọrégèé, ọfọ̀ , àti àfiwé. Ní àkòtán, ìfèdèyàwòrán tí a bá pàdé nínú àwọn ìhun ìpolówó yìí jẹ́ àwọn ìrírí wa ní àwùjọ lójoojúmọ́ . Ní ìkádìí, ìṣẹ́ yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ 168 Alága pé kò sí bí a ti lè lo ète ìpolówó ọjà tó láì jẹ́ pé èdè tí a óò lò gbọdọ̀ jẹ́ àmọ́ - ọ́ n-mọ̀ ṣe àtòjọ ìhun rẹ̀ . Nítorí náà, a gba àwọn apolówó ọjà níyànjú láti máa ṣe àmúlò èdè tó ṣàfihàn ète ìfèdèyàwòrán.

 

https://doi.org/10.32473/ysr.v6i1.130097
PDF
Creative Commons License

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.