Abstract
Ọ̀pọ̀ ọ̀ nà ni àwọn onímọ̀ ti dá lábàá fún síṣe àwárí tàbí ìṣẹ̀ dá ọ̀ rọ̀ -ìperí nínú èdè Yorùbá, lára wọn ni ìsàlàyé, ìhun-ọ̀rọ̀-pọ̀ , ìfisàpẹrẹ, ìlòwe, ọ̀ rọ̀ -àyálò, ìfẹ[1]ìtumọ̀ -lójú àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Ìfẹ-ìtumọ̀ lójú ni ó jẹ ìwádìí yìí lógún nípa wíwá ọ̀ rọ̀ ìperí fún àrùn Kòkòrò-Apa-Sójà-Ara ̣ (KASA) àti Èbólà. A ṣe àgbéyẹ̀ wò 1572 ọ̀ rọ̀ tí Yusuff, Adétúnjí àti Odoje (2017) jẹ́ olóòtú fún, a sì fa àwọn tí wọ́ n fẹ ìtumọ̀ wọn lójú yọ fún ìṣẹ́ ìwádìí ti wa. A ṣàwárí pé oríṣìí mẹ́ tà ọ̀ tọ̀ ọ̀ tọ̀ ni irú àwọn ọ̀ rọ̀ yìí; kò sì sí ìyọnu láti ní òye ìtumọ̀ tuntun tí a wà wọ àwọn ọ̀ rọ̀ náà lọ́ rùn. Ó tilẹ̀ mú ìtumọ̀ gbéetán bá àwọn ọ̀ rọ̀ tuntun tí a lò wọ́ n fún.
This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.