Àrokò Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀ nà Ìbánisọ̀rọ̀ Láàárín Àwọn Babaláwo

Abstract

Àrokò jẹ́ ọ̀ nà ìbánisọ̀ rọ̀ nípa ṣíṣàmúlò àmì tàbí èdè awo. Ìran Yorùbá ò fẹ́ ràn láti máa fi gbogbo ẹnu sọ̀ rọ̀ , nítorí náà wọ́ n nífẹ̀ ẹ́ sí lílo èdè ìjìnlẹ̀ tàbí ohun tí ó ní ìtumọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àṣà wọn fún ìbánisọ̀ rọ̀ . Ọ̀pọ̀ lọpọ̀ onímọ̀ tí ṣiṣẹ́ lórí pàtàkì àrokò láàárín àwọn Yorùbá àmọ́ ọ̀ wọ́ já wọn ò tí dé ibi àrokò láààrín àwọn babaláwo. Pépà yìí ṣe àgbẹ́ yẹ̀ wò àrokò gẹ́ gẹ́ bíi ọ̀ nà ìbánisọ̀ rọ̀ láàárín àwọn babaláwo láwùjọ Yorùbá. Tíọ́ rì ìmọ̀ ìlò-àmi ni a gùnlé láti fi sọ ìtumọ̀ àwọn ohun èlò ìbánisọ̀ rọ̀ láàárín àwọn bábaláwo. Àwọn détà tí a lò ni a gbà lọ́ dọ̀ àwọn àṣàyàn babaláwo, èyí tí a sì ṣàtúpalẹ̀ wọn pẹ̀ lú tíọ́ rì àmúlò. Iṣẹ́ ìwádìí yìí sàlàyé díẹ̀ lára àwọn ohun ìpàrokò, yálà èyí tí o jẹ́ gbólóhùn tàbí èyí tí o jẹ́ ohun èlò àrídìmú tí àwọn babaláwo ń lò fún ìbánisọ̀ rọ̀ awo láàárín ara wọn pẹ̀ lú ọ̀ nà tí wọn ń gbà lò wọ́ n. Pépà yìí tan ìmọ́ lẹ̀ sí orísìírísìí ohun èlò ìpàrokò àti ọ̀ nà tí àwọn babaláwo ń gbà ṣàmúlò wọn fún ìbánisọ̀ rọ̀ láàárín ara wọn. Àpilẹ̀ kọ yìí fi hàn kedere pé ṣíṣe àmúlò àrokò láwùjọ le ṣe ìrànlọ́ wọ́ láti jẹ́ kí á ní àsírí àwọn ohun tí a kò fẹ́ jẹ́ kó hànde. Ó tún jẹ́ kí a mọ̀ pé, kò sí ẹgbẹ́ tàbí àwùjọ kan lábẹ́ àkóso bó ti wù kó rí tí kò ní ọ̀ nà ìbánisọ̀ rọ̀ alárokò láàárín ara wọn.

https://doi.org/10.32473/ysr.v6i1.130094
PDF
Creative Commons License

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.