Àyẹ ̀wò Ìlò Àpólà- Orúkọ Aṣẹ̀dá Nínú Ìwé Ìtànàròsọ Àjà Ló Lẹrù

Abstract

Ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀ dá-èdè (linguistics) àti lítíréṣọ̀ ti wọnú ara wọn tí ó jẹ́ pé a fẹ́ rẹ̀ má le ya ọ̀ kan kúrò lára èkejì. Èròǹgbà iṣẹ́ yìí ni láti fi ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàárin ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè àti lítíréṣọ hán. Láti ṣe èyí a yan ìwé-ìtàn –àròsọ Àjà Ló Lẹrù tí Òkédìjí kọ láàyò, a sì fi ẹ̀ka -ẹ̀kọ́ ìmọ̀ mọfọ́lọ́jì tí í ṣe ẹ̀kọ́ ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè ṣe àyẹ̀wò ìlò ọ̀rọ̀-orúkọ (OR) aṣẹ̀dá nínú ìwé ìtàn-àròsọ yìí. Lára ọgbọ́n ìwádìí tí a lò ni pé a ka ìwé ìtàn àròsọ Àjà Ló Lẹrù dáadáa, a sì ṣe àfàyọ àwọn OR aṣẹ̀dá jáde nínú rẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni a ṣe àkójọpọ̀ àti ìtúpalẹ̀ àwọn OR aṣẹ̀dá wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìṣẹ̀dá wọn nínú ẹ̀kọ́ mọfọ́lọ́jì. A ṣe àyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ mọfọ́lọ́jì àti ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìsọwọ́lò-èdè àti lítíréṣọ̀ (stylistics) láti mú kí iṣẹ́ yìí kún ojú òsùnwọ̀n. Ní ìparí iṣẹ́ yìí, a rí i pé ipa tí ìlò àwọn OR aṣẹ̀ dá nínú ìwé ìtàn-àrosọ yìí kó kò kéré rárá. Àwọn OR aṣẹ̀dá yìí jẹ́ èròjà tí ó mú èdè ìwé náà kún, kí ó ki tí ó sì fi àwòrán àwọn ẹ̀dá ìtàn rẹ̀ hàn. Bí kò bá sí àwọn ẹ̀ka ìmọ̀ lítíréṣọ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ aṣẹ̀dá pàápàá OR nínu ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ni kò ní wúlò bí a ṣe rí i nínú iṣẹ́ àpilẹ̀ kọ yíí. Lítíréṣọ̀ tún wá di orísun àfikún àká ọ̀ rọ̀ nínú ìmọ̀ ẹ̀ dá-èdè.

https://doi.org/10.32473/ysr.v6i1.130089
PDF
Creative Commons License

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.

Metrics

Metrics Loading ...