Ìlò Èébú Nínú Àwọn Ìtàn-àròsọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Òkédìjí

Abstract

Ògúnṣínà (1992), Adébọ̀wálé (1994) àti Ìṣọ̀lá (1995) ti ṣe àlàyé lórí ìlò èdè Òkédìjí nínú ìtàn-àròsọ Àjà Ló Lẹrù, Àgbàlagbà Akàn àti Ká Rìn Ká Pọ̀ ṣùgbọ́n kò sí lámèyítọ́ tó yẹ ìlò èébú wò nínú àwọn ìwé náà tàbí ti òǹkọ̀ wé ìtàn-àròsọ Yorùbá mìíràn. Iṣẹ́ yìí ṣe àyẹ̀ wò ìlò èébú nínú ìtàn-àròsọ Òkédìjí, ó sì lo ọgbọ́ n ìwádìí kíka àwọn ìwé náà ní àkàtúnkà láti ṣe àfàyọ àti àkójọpọ̀ gbogbo èébú tó súyọ kí a tó ṣe ìtúpalẹ̀ wọn. Tíọ́rì ọ̀nà ìṣafọ̀ tó jẹmọ́ èròǹgbà aṣafọ̀ àti ìmọ̀lára òsùnsùn-afọ̀ nípa afọ̀ la fi ṣe àlàyé wa. Ìgbà ọ̀ọ́dúnrún àti ọ̀kandínláàádọ́rùn-ún ni Òkédìjí ti lo èébú nínú àwọn ìtàn-àròsọ rẹ̀, ọ̀nà ìṣafọ̀ méjì tó gbà ṣe àgbékalẹ̀ èébú ni ìṣafọ̀ sínú àti ìṣafọ̀ síta. Ìsọ̀ rí èébú wọ̀ nyí lè jẹ́ èébú ti ẹlẹ́ yọ-ọ̀ rọ̀ , alápòólà, odindi gbólóhùn, oníbéèrè, òwe àti oríkì ajẹméèébú. Iṣẹ́ tí àwọn aṣafọ̀ fi èébú ṣe nínú ìsọ̀ rọ̀ gbèsì la fi kásẹ̀ àlàyé wa.

https://doi.org/10.32473/ysr.v6i1.130088
PDF
Creative Commons License

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial 4.0 International License.

Metrics

Metrics Loading ...